-
Ẹ́kísódù 26:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá gbọọrọ, ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan àgọ́ ìjọsìn náà,+ 27 ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn, ní ẹ̀yìn. 28 Kí ọ̀pá gbọọrọ tó wà láàárín gba àárín àwọn férémù náà kọjá láti ìkángun dé ìkángun.
-