-
Ẹ́kísódù 25:10-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Kí wọ́n fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjì ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 11 Kí o wá fi ògidì wúrà bò ó.+ Kí o fi bò ó nínú àti níta, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká.+ 12 Kí o fi wúrà rọ òrùka mẹ́rin fún un, kí o sì fi wọ́n síbi òkè ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ kan àti òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ kejì. 13 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.+ 14 O máa ki àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àpótí náà, kí ẹ lè máa fi gbé Àpótí náà. 15 Inú àwọn òrùka Àpótí náà ni kí àwọn ọ̀pá náà máa wà; ẹ má ṣe yọ wọ́n kúrò níbẹ̀.+
-