-
Ẹ́kísódù 7:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Lójú ẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́. Ó na ọ̀pá náà sókè, ó sì fi lu omi odò Náílì níṣojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, gbogbo omi odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.+
-
-
Ẹ́kísódù 8:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Áárónì na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì fi lu erùpẹ̀, àwọn kòkòrò náà wá bo èèyàn àti ẹranko. Gbogbo erùpẹ̀ di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 18 Àwọn àlùfáà onídán náà gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà, wọ́n fẹ́ fi agbára òkùnkùn wọn mú kòkòrò jáde,+ àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Àwọn kòkòrò náà bo èèyàn àti ẹranko.
-
-
Ẹ́kísódù 9:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àwọn àlùfáà onídán kò lè dúró níwájú Mósè torí eéwo náà, torí eéwo ti bo àwọn àlùfáà náà àti gbogbo ará Íjíbítì.+
-
-
2 Tímótì 3:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Bí Jánésì àti Jáńbérì ṣe ta ko Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn yìí ṣe ń ta ko òtítọ́ ṣáá. Ìrònú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dìbàjẹ́, ìgbàgbọ́ wọn ò sì ní ìtẹ́wọ́gbà.
-