-
Hébérù 12:18-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Torí kì í ṣe ohun tó ṣeé fọwọ́ bà,+ tí a sì dáná sí,+ lẹ sún mọ́, kì í ṣe ìkùukùu* tó ṣú dùdù àti òkùnkùn biribiri àti ìjì,+ 19 àti ìró kàkàkí+ àti ohùn tó ń sọ̀rọ̀,+ èyí tó jẹ́ pé nígbà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ọ, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé ká má ṣe bá àwọn sọ̀rọ̀ mọ́.+ 20 Torí wọn ò lè mú àṣẹ náà mọ́ra pé: “Tí ẹranko pàápàá bá fara kan òkè náà, ẹ gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta.”+ 21 Bákan náà, ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù débi pé Mósè sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà mí, jìnnìjìnnì sì bò mí.”+
-