Ẹ́kísódù 15:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Jagunjagun tó lágbára ni Jèhófà.+ Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.+ Sáàmù 96:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀;+Ẹ mú ẹ̀bùn dání wá sínú àwọn àgbàlá rẹ̀. Sáàmù 135:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Jèhófà, orúkọ rẹ wà títí láé. Jèhófà, òkìkí rẹ yóò máa kàn* láti ìran dé ìran.+ Hósíà 12:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun+ ni,Jèhófà sì ni orúkọ tí a fi ń rántí rẹ̀.*+ Jòhánù 17:26 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 26 Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n,+ kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”+ Róòmù 10:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Nítorí “gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà* yóò rí ìgbàlà.”+
26 Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n,+ kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”+