-
Ẹ́kísódù 2:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, ó jáde, ó sì rí àwọn ọkùnrin Hébérù méjì tó ń bára wọn jà. Ó wá sọ fún ẹni tó jẹ̀bi pé: “Kí ló dé tí o lu ọ̀rẹ́ rẹ?”+ 14 Nìyẹn bá fèsì pé: “Ta ló fi ọ́ ṣe olórí àti onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ọmọ Íjíbítì yẹn ni?”+ Ẹ̀rù wá ba Mósè, ó sì sọ pé: “Ó dájú pé àwọn èèyàn ti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí!”
-