-
Ẹ́kísódù 30:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àwọn lọ́fínńdà tó dáa jù: ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n òjíá dídì àti sínámónì dídùn tó jẹ́ ìdajì rẹ̀, ìyẹn igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì dídùn 24 àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n kaṣíà, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ pẹ̀lú òróró ólífì tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan. 25 Kí o wá fi ṣe òróró àfiyanni mímọ́; kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa.*+ Òróró àfiyanni mímọ́ ni yóò jẹ́.
-