-
2 Kíróníkà 2:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Wò ó, mo ti rán ọkùnrin ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà kan sí ọ, ó ní òye, Hiramu-ábì+ ni orúkọ rẹ̀, 14 ó jẹ́ ọmọ obìnrin kan tó wá látinú ẹ̀yà Dánì, àmọ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ará Tírè; ó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà, irin, òkúta, igi gẹdú, òwú aláwọ̀ pọ́pù, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, aṣọ àtàtà àti aṣọ rírẹ̀dòdò.+ Ó lè fín oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà, ó sì lè ṣe iṣẹ́ ọnà èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un.+ Ó máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà rẹ àti àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà olúwa mi Dáfídì bàbá rẹ.
-