10 “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.
13 “‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé láàárín yín bá ń ṣọdẹ, tó sì mú ẹran ìgbẹ́ tàbí ẹyẹ tí ẹ lè jẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde,+ kó sì fi erùpẹ̀ bò ó.
29 láti máa ta kété sí àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ láti máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀,+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti sí ìṣekúṣe.*+ Tí ẹ bá ń yẹra fún àwọn nǹkan yìí délẹ̀délẹ̀, ẹ ó láásìkí. Kí ara yín ó le o!”*