10 “‘Tó bá fẹ́ mú ẹran wá láti fi rú ẹbọ sísun látinú agbo ẹran,+ lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́, kó jẹ́ akọ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ 11 Kí wọ́n pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+