2 Kó wá gbé e wá fún àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun náà tí wọ́n pò mọ́ òróró àti gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,*+ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*
15 Kí ọ̀kan lára wọn bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun tó kúnná nínú ọrẹ ọkà àti díẹ̀ lára òróró rẹ̀ àti gbogbo oje igi tùràrí tó wà lórí ọrẹ ọkà, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ.*+