17 “Kí ló dé tí ẹ ò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní ibi mímọ́,+ ṣebí ohun mímọ́ jù lọ ni, ó sì ti fún yín, kí ẹ lè ru ẹ̀bi àpéjọ náà, kí ẹ sì ṣe ètùtù fún wọn níwájú Jèhófà? 18 Ẹ wò ó! Ẹ ò tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú ibi mímọ́.+ Ó yẹ kí ẹ ti jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, bí àṣẹ tí mo gbà.”