2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ yan àwọn ìlú ààbò fún ara yín,+ èyí tí mo ní kí Mósè sọ fún yín nípa rẹ̀, 3 kí ẹni tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn tàbí tó ṣèèṣì pa èèyàn lè sá lọ síbẹ̀. Àwọn ìlú náà á sì jẹ́ ìlú ààbò fún yín lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.+