30 Élísáfánì ọmọ Úsíélì+ ni ìjòyè agbo ilé ní ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì. 31 Ojúṣe wọn ni pé kí wọ́n máa bójú tó Àpótí,+ tábìlì,+ ọ̀pá fìtílà,+ àwọn pẹpẹ,+ àwọn ohun èlò+ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, aṣọ tí wọ́n ta+ sí ẹnu ọ̀nà àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí.+