-
Diutarónómì 1:34-38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 “Ní gbogbo ìgbà yẹn, Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ̀ ń sọ, inú sì bí i gidigidi, ó wá búra pé,+ 35 ‘Ìkankan nínú àwọn èèyàn yìí tí wọ́n wà lára ìran búburú yìí kò ní rí ilẹ̀ dáradára tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá yín,+ 36 àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè. Òun máa rí i, mo sì máa fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ilẹ̀ tó rìn lórí rẹ̀, torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà.*+ 37 (Torí yín ni Jèhófà tiẹ̀ ṣe bínú sí mi, ó ní, “Ìwọ náà ò ní wọ ibẹ̀.+ 38 Jóṣúà ọmọ Núnì, tó máa ń dúró níwájú rẹ+ ló máa wọ ilẹ̀ náà.+ Sọ ọ́ di alágbára,*+ torí òun ló máa mú kí Ísírẹ́lì jogún rẹ̀.”)
-