13 Bálákì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ sí ibòmíì tí o ti lè rí wọn. Díẹ̀ nínú wọn ni wàá rí; o ò ní rí gbogbo wọn. Bá mi gégùn-ún fún wọn láti ibẹ̀.”+ 14 Torí náà, ó mú un lọ sí pápá Sófímù, ní orí Písígà,+ ó mọ pẹpẹ méje, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan.