32 Ẹ̀yin ìjọba ayé, ẹ kọrin sí Ọlọ́run,+
Ẹ fi orin yin Jèhófà, (Sélà)
33 Ẹni tó ń gun ọ̀run àwọn ọ̀run tó ti wà láti ayébáyé.+
Wò ó! Ó fi ohùn rẹ̀ sán ààrá, ohùn rẹ̀ alágbára ńlá.
34 Ti Ọlọ́run ni agbára.+
Ọlá ńlá rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lì
Àti okun rẹ̀ lójú ọ̀run.