-
Ẹ́kísódù 20:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+
-
-
Diutarónómì 19:16-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Tí ẹlẹ́rìí èké kan bá jẹ́rìí lòdì sí ẹnì kan, tó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe ohun tí kò dáa,+ 17 kí àwọn méjèèjì tó ń bára wọn fa ọ̀rọ̀ wá dúró níwájú Jèhófà, níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí wọ́n á máa dájọ́ nígbà yẹn.+ 18 Kí àwọn adájọ́ náà wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa,+ tó bá jẹ́ ẹlẹ́rìí èké ni ẹni tó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fẹ̀sùn èké kan arákùnrin rẹ̀, 19 ohun tó gbèrò láti ṣe sí arákùnrin rẹ̀ ni kí ẹ ṣe sí i,+ kí ẹ sì mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+
-