-
Nọ́ńbà 6:23-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Bí ẹ ó ṣe máa súre+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí. Kí ẹ sọ fún wọn pé:
24 “Kí Jèhófà bù kún ọ,+ kó sì pa ọ́ mọ́.
25 Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ+ lára, kó sì ṣojúure sí ọ.
26 Kí Jèhófà bojú wò ọ́, kó sì fún ọ ní àlàáfíà.”’+
27 Kí wọ́n sì fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí n lè bù kún wọn.”+
-
-
2 Kíróníkà 30:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Níkẹyìn, àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ àlùfáà dìde dúró, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn náà;+ Ọlọ́run gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì dé ibi mímọ́ tó ń gbé ní ọ̀run.
-