13 Torí tèmi+ ni gbogbo àkọ́bí. Lọ́jọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ mo ya gbogbo àkọ́bí ní Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara mi, látorí èèyàn dórí ẹranko.+ Wọ́n á di tèmi. Èmi ni Jèhófà.”
15 “Àkọ́bí gbogbo ohun alààyè,*+ tí wọ́n bá mú wá fún Jèhófà, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko, yóò di tìrẹ. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ ra àkọ́bí èèyàn+ pa dà, kí o sì tún ra àkọ́bí àwọn ẹran tó jẹ́ aláìmọ́ pa dà.+
17 Akọ màlúù tó jẹ́ àkọ́bí tàbí akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tó jẹ́ àkọ́bí tàbí àkọ́bí ewúrẹ́ nìkan ni kí o má rà pa dà.+ Wọ́n jẹ́ ohun mímọ́. Kí o wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ,+ kí o sì mú kí ọ̀rá wọn rú èéfín bí ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà.+