-
Jóṣúà 10:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Adoni-sédékì ọba Jerúsálẹ́mù wá ránṣẹ́ sí Hóhámù ọba Hébúrónì,+ Pírámù ọba Jámútì, Jáfíà ọba Lákíṣì àti Débírì ọba Ẹ́gílónì+ pé: 4 “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́, ká lè jọ gbógun ja Gíbíónì, torí ó ti bá Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àdéhùn àlàáfíà.”+ 5 Ni àwọn ọba Ámórì+ márààrún bá kóra jọ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn, ìyẹn ọba Jerúsálẹ́mù, ọba Hébúrónì, ọba Jámútì, ọba Lákíṣì àti ọba Ẹ́gílónì, wọ́n sì lọ pàgọ́ ti Gíbíónì láti bá a jà.
-