-
Ẹ́kísódù 13:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “Ní ọjọ́ iwájú, tí ọmọ yín bá bi yín pé, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ kí ẹ sọ fún un pé, ‘Ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú wa kúrò ní Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+
-
-
Diutarónómì 6:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Lọ́jọ́ iwájú, tí ọmọ rẹ bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ àwọn ìránnilétí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run wa pa láṣẹ fún yín?’ 21 kí o sọ fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú Fáráò ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa jáde ní Íjíbítì.
-