-
Jóṣúà 15:16-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Kélẹ́bù sọ pé: “Ẹni tó bá pa Kiriati-séférì run, tó sì gbà á, màá fún un ní Ákúsà ọmọ mi pé kó fi ṣe aya.” 17 Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì,+ arákùnrin Kélẹ́bù sì gbà á. Torí náà, ó fún un ní Ákúsà+ ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 18 Nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sílé, ó rọ ọmọkùnrin náà pé kó tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ bàbá òun. Ọmọbìnrin náà wá sọ̀ kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.* Kélẹ́bù sì bi í pé: “Kí lo fẹ́?”+ 19 Ó sọ pé: “Jọ̀ọ́, bù kún mi, o ti fún mi ní ilẹ̀ kan ní gúúsù;* tún fún mi ní Guloti-máímù.”* Torí náà, ó fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀.
-