-
Àwọn Onídàájọ́ 4:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àmọ́ Jáẹ́lì ìyàwó Hébà mú èèkàn àgọ́, ó sì mú òòlù dání. Nígbà tí ọkùnrin náà ti sùn lọ fọnfọn, tó sì ti rẹ̀ ẹ́, Jáẹ́lì yọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó gbá èèkàn àgọ́ náà wọnú ẹ̀bátí rẹ̀, ó gbá a wọlẹ̀, ọkùnrin náà sì kú.+
22 Bárákì wá Sísérà débẹ̀, Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Máa bọ̀, jẹ́ kí n fi ọkùnrin tí ò ń wá hàn ọ́.” Bárákì bá tẹ̀ lé e wọlé, ó sì rí òkú Sísérà nílẹ̀, pẹ̀lú èèkàn àgọ́ tí Jáẹ́lì gbá wọnú ẹ̀bátí rẹ̀.
-