-
Jẹ́nẹ́sísì 18:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sáré lọ síbi tí agbo ẹran wà, ó sì mú akọ ọmọ màlúù kan tó dára, tí ara rẹ̀ sì rọ̀. Ó fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì yára lọ sè é.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 6:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Jọ̀ọ́, má ṣe kúrò níbí títí màá fi gbé ẹ̀bùn mi wá síwájú rẹ.”+ Ó fèsì pé: “Màá dúró síbí títí wàá fi dé.” 19 Gídíónì wá wọlé lọ, ó se ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun+ tó jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà* kan ṣe búrẹ́dì aláìwú. Ó kó ẹran náà sínú apẹ̀rẹ̀, ó sì rọ omi rẹ̀ sínú ìkòkò; ó wá gbé e lọ bá a, ó sì gbé e síwájú rẹ̀ lábẹ́ igi ńlá náà.
-