-
Jóṣúà 7:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Jóṣúà wá dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, ó ní kí Ísírẹ́lì wá ní ẹ̀yà-ẹ̀yà, a sì mú ẹ̀yà Júdà. 17 Ó ní kí àwọn ìdílé Júdà wá, a sì mú ìdílé àwọn ọmọ Síírà,+ lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ọkùnrin ní ìdílé àwọn ọmọ Síírà wá lọ́kọ̀ọ̀kan, a sì mú Sábídì. 18 Níkẹyìn, ó ní kí àwọn ọkùnrin ní agboolé Sábídí wá lọ́kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Sábídí, ọmọ Síírà látinú ẹ̀yà Júdà.+
-