-
2 Sámúẹ́lì 5:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, àmọ́ Ó sọ pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà. 24 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o gbé ìgbésẹ̀ ní kíá, nítorí Jèhófà yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.”
-
-
2 Àwọn Ọba 6:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà tí ìránṣẹ́* èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ dìde ní àárọ̀ kùtù, tí ó sì jáde, ó rí i tí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yí ìlú náà ká. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Áà, ọ̀gá mi! Kí la máa ṣe?” 16 Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Má bẹ̀rù!+ Torí pé àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.”+
-