39 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o dárí jì wọ́n,+ kí o sì gbé ìgbésẹ̀; kí o san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ nítorí pé o mọ ọkàn rẹ̀ (ìwọ nìkan lo mọ ọkàn gbogbo èèyàn lóòótọ́),+
9 “Ìwọ Sólómọ́nì ọmọ mi, mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn*+ àti inú dídùn* sìn ín, nítorí gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá,+ ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.+ Tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun,+ àmọ́ tí o bá fi í sílẹ̀, á kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ títí láé.+