16 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Ìgbà wo lo máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù dà,+ ní báyìí tí mo ti kọ Sọ́ọ̀lù pé kí ó má ṣe jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì mọ́?+ Rọ òróró sínú ìwo,+ kí o sì lọ. Màá rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè+ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí mo ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún mi.”+