-
1 Sámúẹ́lì 17:45, 46Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Dáfídì fún Filísínì náà lésì pé: “Ìwọ ń mú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín*+ bọ̀ wá bá mi jà, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ wá bá ọ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ Ọlọ́run ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí o pẹ̀gàn.*+ 46 Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ màá mú ọ balẹ̀, màá sì gé orí rẹ kúrò. Lónìí yìí kan náà, màá fi òkú àwọn tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran inú igbó; gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní Ísírẹ́lì.+
-