11 Níkẹyìn, Sámúẹ́lì béèrè lọ́wọ́ Jésè pé: “Ṣé gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ nìyí?” Ó fèsì pé: “Èyí tó kéré jù+ ṣì wà níta; ó kó àwọn àgùntàn lọ jẹ koríko.”+ Ni Sámúẹ́lì bá sọ fún Jésè pé: “Ní kí wọ́n lọ pè é wá, torí ó dìgbà tó bá dé ká tó jókòó láti jẹun.”