-
Ẹ́kísódù 1:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àwọn agbẹ̀bí náà sọ fún Fáráò pé: “Àwọn obìnrin Hébérù ò dà bí àwọn obìnrin Íjíbítì. Wọ́n lágbára, wọ́n sì ti máa ń bímọ kí agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
-
-
Jóṣúà 2:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ni ọba Jẹ́ríkò bá ránṣẹ́ sí Ráhábù pé: “Mú àwọn ọkùnrin tó wá síbí jáde, àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, torí ṣe ni wọ́n wá ṣe amí gbogbo ilẹ̀ yìí.”
4 Àmọ́ obìnrin náà mú àwọn ọkùnrin méjèèjì, ó sì fi wọ́n pa mọ́. Ó wá sọ pé: “Òótọ́ ni àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi, àmọ́ mi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá. 5 Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, tó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ẹnubodè ìlú ni àwọn ọkùnrin náà jáde. Mi ò mọ ibi tí àwọn ọkùnrin náà lọ, àmọ́ tí ẹ bá tètè sá tẹ̀ lé wọn, ẹ máa bá wọn.”
-
-
1 Sámúẹ́lì 19:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Míkálì sọ Dáfídì kalẹ̀ gba ojú fèrèsé,* kí ó lè sá àsálà.
-
-
1 Sámúẹ́lì 19:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Sọ́ọ̀lù wá rán àwọn òjíṣẹ́ láti mú Dáfídì, àmọ́ Míkálì sọ pé: “Ara rẹ̀ ò yá.”
-
-
1 Sámúẹ́lì 21:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Dáfídì dá àlùfáà Áhímélékì lóhùn pé: “Ọba ní kí n ṣe ohun kan, àmọ́ ó sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ tí mo rán ọ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ.’ Torí náà, mo bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ṣe àdéhùn pé ká pàdé níbì kan.
-