-
1 Àwọn Ọba 2:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ìgbà náà ni wọ́n wá sọ fún Ọba Sólómọ́nì pé: “Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Jèhófà, ó sì wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ.” Torí náà, Sólómọ́nì rán Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà pé: “Lọ pa á!”
-
-
1 Kíróníkà 27:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Olórí àwùjọ kẹta tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ ní oṣù kẹta ni Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ olórí àlùfáà, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 6 Bẹnáyà yìí jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú lára àwọn ọgbọ̀n (30) náà, òun ló ń bójú tó àwọn ọgbọ̀n (30) náà, Ámísábádì ọmọ rẹ̀ ló sì ń bójú tó àwùjọ rẹ̀.
-