-
1 Kíróníkà 21:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Nígbà náà, Jèhófà rán àjàkálẹ̀ àrùn+ sí Ísírẹ́lì, tó fi jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) èèyàn lára Ísírẹ́lì kú.+ 15 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tòótọ́ rán áńgẹ́lì kan sí Jerúsálẹ́mù láti pa á run; àmọ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà rí i, ó sì pèrò dà* lórí àjálù náà,+ ó sọ fún áńgẹ́lì tó ń pani run náà pé: “Ó tó gẹ́ẹ́!+ Gbé ọwọ́ rẹ wálẹ̀.” Áńgẹ́lì Jèhófà dúró nítòsí ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.+
-