-
Diutarónómì 4:41-43Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
41 Nígbà yẹn, Mósè ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.+ 42 Tí apààyàn èyíkéyìí bá ṣèèṣì pa ọmọnìkejì rẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀,+ kó sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kí wọ́n má bàa pa á.+ 43 Àwọn ìlú náà ni Bésérì+ ní aginjù, lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì fún àwọn ọmọ Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì fún àwọn ọmọ Mánásè.+
-
-
1 Àwọn Ọba 22:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa la ni Ramoti-gílíádì?+ Síbẹ̀, à ń wò, a ò ṣe nǹkan kan láti gbà á lọ́wọ́ ọba Síríà.”
-