9 Wò ó! Wàá bí ọmọkùnrin kan+ tó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà,* màá sì fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká,+ Sólómọ́nì*+ ni orúkọ tí a máa pè é, màá sì fi àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ jíǹkí Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé rẹ̀.+
29Ọba Dáfídì sọ fún gbogbo ìjọ náà pé: “Sólómọ́nì ọmọ mi, ẹni tí Ọlọ́run yàn,+ jẹ́ ọ̀dọ́, kò ní ìrírí,*+ iṣẹ́ náà sì pọ̀, torí pé kì í ṣe tẹ́ńpìlì* èèyàn, àmọ́ ti Jèhófà Ọlọ́run ni.+