2 Sámúẹ́lì 7:16, 17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 16 Ilé rẹ àti ìjọba rẹ máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí láé níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ á sì fìdí múlẹ̀ títí láé.”’”+ 17 Nátánì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ìran tó rí+ fún Dáfídì. 1 Àwọn Ọba 2:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Jèhófà á sì mú ìlérí tó ṣe nípa mi ṣẹ, pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá fiyè sí ọ̀nà wọn, láti fi òtítọ́ rìn níwájú mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara* wọn,+ kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ* tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+ Sáàmù 89:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Mo ti rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;+Mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án.+ Sáàmù 89:29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 29 Màá fìdí àwọn ọmọ* rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,Màá sì mú kí ìtẹ́ rẹ̀ wà títí lọ bí ọ̀run.+
16 Ilé rẹ àti ìjọba rẹ máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí láé níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ á sì fìdí múlẹ̀ títí láé.”’”+ 17 Nátánì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ìran tó rí+ fún Dáfídì.
4 Jèhófà á sì mú ìlérí tó ṣe nípa mi ṣẹ, pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá fiyè sí ọ̀nà wọn, láti fi òtítọ́ rìn níwájú mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara* wọn,+ kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ* tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+