16 Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba ò gbọ́ tiwọn, àwọn èèyàn náà fún ọba lésì pé: “Kí ló pa àwa àti Dáfídì pọ̀? A ò ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè. Lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì. Máa mójú tó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì!” Bí Ísírẹ́lì ṣe pa dà sí ilé wọn nìyẹn.+