-
1 Àwọn Ọba 13:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Torí náà, ó sin òkú náà sínú ibojì ti ara rẹ̀, wọ́n sì ń sunkún nítorí rẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Ó mà ṣe o, arákùnrin mi!”
-
-
2 Àwọn Ọba 23:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Èwo ni òkúta sàréè tí mò ń wò níbẹ̀ yẹn?” Àwọn èèyàn ìlú náà bá sọ fún un pé: “Sàréè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó wá láti Júdà+ ni, ẹni tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí o ṣe sí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì.” 18 Nítorí náà, ó sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má fọwọ́ kan egungun rẹ̀, ẹ fi sílẹ̀ bó ṣe wà.” Torí náà, wọn ò fọwọ́ kan egungun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ò fọwọ́ kan egungun wòlíì tó wá láti Samáríà.+
-