-
Diutarónómì 12:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+ 6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+
-
-
1 Àwọn Ọba 8:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, mi ò yan ìlú kankan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí màá kọ́ ilé sí fún orúkọ mi, kí ó lè máa wà níbẹ̀,+ ṣùgbọ́n mo ti yan Dáfídì láti ṣe olórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’ 17 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
-