-
2 Kíróníkà 12:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, nítorí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. 3 Ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba (1,200) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn agẹṣin pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí kò níye, tí wọ́n bá a wá láti Íjíbítì, ìyẹn àwọn ará Líbíà, Súkímù àti àwọn ará Etiópíà.+ 4 Ó gba àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà, níkẹyìn, ó dé Jerúsálẹ́mù.
-