-
2 Àwọn Ọba 3:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò ní rí ìjì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí òjò; síbẹ̀, omi máa kún àfonífojì yìí,+ ẹ ó sì mu látinú rẹ̀, ẹ̀yin àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín pẹ̀lú àwọn ẹran míì tí ẹ ní.”’
-
-
2 Àwọn Ọba 4:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Lẹ́yìn náà kí o wọlé, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ àti àwọn ọmọ rẹ. Rọ òróró sínú àwọn ohun èlò náà, kí o sì gbé àwọn tó ti kún sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”
-
-
2 Àwọn Ọba 4:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nítorí náà, ó wọlé, ó sì sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Èlíṣà wá sọ pé: “Lọ ta òróró náà, kí o fi san gbèsè rẹ, kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ sì máa fi ohun tó kù tọ́jú ara yín.”
-
-
2 Àwọn Ọba 6:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Bí ọ̀kan lára wọn ṣe ń gé igi lọ́wọ́, irin àáké rẹ̀ já bọ́ sínú omi, ó sì kígbe pé: “Áà, ọ̀gá mi, ńṣe la yá a!” 6 Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ wá bi í pé: “Ibo ló bọ́ sí?” Torí náà, ó fi ibẹ̀ hàn án. Ó wá gé igi kan, ó sọ ọ́ sí ibẹ̀, ó sì mú kí irin àáké náà léfòó. 7 Ó sọ pé: “Mú un jáde.” Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un.
-