-
Nọ́ńbà 21:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ṣe ejò kan tó dà bí ejò olóró,* kí o sì gbé e kọ́ sára òpó. Tí ejò bá ṣán ẹnikẹ́ni, onítọ̀hún máa ní láti wò ó kó má bàa kú.” 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fi bàbà ṣe ejò+ kan, ó sì gbé e kọ́ sára òpó+ náà. Nígbàkigbà tí ejò bá ṣán ẹnì kan, tó sì wo ejò bàbà náà, ẹni náà ò ní kú.+
-