-
Àìsáyà 22:20-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “‘Ní ọjọ́ yẹn, màá pe ìránṣẹ́ mi, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, 21 màá wọ aṣọ rẹ fún un, màá de ọ̀já rẹ mọ́ ọn pinpin,+ màá sì gbé àṣẹ* rẹ lé e lọ́wọ́. Ó máa di bàbá àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ilé Júdà. 22 Màá sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì+ sí èjìká rẹ̀. Tó bá ṣí ibì kan, ẹnì kankan ò ní tì í; tó bá sì ti ibì kan, ẹnì kankan ò ní ṣí i. 23 Màá kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn sí ibi tó máa wà títí lọ, ó sì máa dà bí ìtẹ́ ògo fún ilé bàbá rẹ̀. 24 Wọ́n máa gbé gbogbo ògo* ilé bàbá rẹ̀ kọ́ sára rẹ̀, àwọn àtọmọdọ́mọ àtàwọn ọmọ,* gbogbo ohun èlò kéékèèké, àwọn ohun èlò tó rí bí abọ́, títí kan gbogbo ìṣà ńlá.
-