30 “Àwọn alágídí ọmọ gbé,”+ ni Jèhófà wí,
“Àwọn tó ń ṣe ohun tí mi ò ní lọ́kàn,+
Tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀, àmọ́ tí kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,
Kí wọ́n lè dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.
2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,+
Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,
Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!