2 Ó kéde sórí pẹpẹ náà bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, ó ní: “Ìwọ pẹpẹ, pẹpẹ! Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó! Wọ́n á bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jòsáyà+ ní ilé Dáfídì! Ó máa fi àwọn àlùfáà ibi gíga rúbọ lórí rẹ, ìyẹn àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín lórí rẹ, ó sì máa sun egungun èèyàn lórí rẹ.’”+