6 Ní àwọn ìlú Mánásè, Éfúrémù,+ Síméónì àti títí dé Náfútálì, ní àwọn ibi tó ti di àwókù tó yí wọn ká, 7 ó wó àwọn pẹpẹ, ó fọ́ àwọn òpó òrìṣà àti àwọn ère gbígbẹ́ túútúú,+ ó sì lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú; ó gé gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí lulẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù.