-
Jeremáyà 39:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ní ọdún kọkànlá Sedekáyà, ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé.+
-
-
Jeremáyà 39:4-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nígbà tí Sedekáyà ọba Júdà àti gbogbo ọmọ ogun rí wọn, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ,+ wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba jáde kúrò nínú ìlú náà lóru, wọ́n gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì kọjá, wọ́n sì gba ọ̀nà Árábà jáde.+ 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé wọn, wọ́n sì bá Sedekáyà ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò.+ Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ ibẹ̀ ló sì ti dá a lẹ́jọ́. 6 Ọba Bábílónì ní kí wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀ ní Ríbúlà, ọba Bábílónì sì ní kí wọ́n pa gbogbo èèyàn pàtàkì Júdà.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é kó lè mú un wá sí Bábílónì.+
-