9 Obìnrin náà wá sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Mo mọ̀ pé èèyàn mímọ́ Ọlọ́run ni ọkùnrin tó máa ń gba ibí kọjá déédéé. 10 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí òrùlé,+ kí a sì gbé ibùsùn, tábìlì, àga àti ọ̀pá fìtílà kan síbẹ̀ fún un. Nígbàkigbà tó bá wá sọ́dọ̀ wa, á lè dúró síbẹ̀.”+