2 Kíróníkà 16:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+ Sáàmù 18:32 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 32 Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹni tó ń gbé agbára wọ̀ mí,+Yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé.+ Àìsáyà 40:29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 29 Ó ń fún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára,Ó sì ń fún àwọn tí kò lókun* ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun.+
9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+